Lúùkù 7:40-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Símónì, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”

41. “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbésè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.

42. Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríji àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, tani yóò fẹ́ ẹ jù?”

Lúùkù 7