Lúùkù 4:42-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jésù sì jáde lọ ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má baà lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

43. Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàì má wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.”

44. Ó sì ń wàásù nínú sínágọ́gù ti Jùdíà.

Lúùkù 4