9. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá gbúròó ogun àti ìdágìrì, ẹ má ṣe fòyà; nítorí nǹkan wọ̀nyí ní láti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀: ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe lójúkan náà.”
10. Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè, àti ìjọba sí ìjọba.
11. Ilẹ̀ríri ilẹ̀ ńlá yóò sì wà káàkiri, àti ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn; ohun ẹ̀rù, àti àmì ńlá yóò sì ti ọ̀run wá.
12. “Ṣùgbọ́n ṣáájú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, wọn ó nawọ́ mú yín, wọn ó sì ṣe inúnibíni sí yín, wọn ó mú yín lọ sí sínágọ́gù, àti sínú túbú, wọn ó mú yín lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba àti àwọn ìjòyè nítorí orúkọ mi.
13. Yóò sì padà di ẹ̀rí fún yín.
14. Nítorí náà ẹ pinnu rẹ̀ lọ́kàn yín pé ẹ yóò ronú ṣáájú, bí ẹ ó ti dáhùn.
15. Nítorí tí èmi ó fún yín ní ẹnu àti ọgbọ́n, tí gbogbo àwọn ọ̀tá yín kì yóò lè sọ̀rọ̀-òdì sí, tí wọn kì yóò sì lè kò lójú.
16. A ó sì fi yín hàn láti ọwọ́ àwọn òbí yín wá, àti àwọn arákùnrin, àti àwọn ìbátan, àti àwọn ọ̀ré; on ó sì mú kì a pa nínú yín.
17. A ó sì kórìíra yín lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí orúkọ mi.
18. Ṣùgbọ́n irun orí yín kan kì yóò ṣègbé.
19. Nínú sùúrù yín ni ẹ̀yin ó jèrè ọkàn yín.