8. Sákéù sì dìde, ó sì wí fún Olúwa pé, “Wòó, Olúwa, ààbọ̀ ohun ìní mi ni mo fifún talákà; bí mo bá sì fi èké gba ohun kan lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, èmi san án padà ní ìlọ́po mẹ́rin!”
9. Jésù sì wí fún un pé, “Lóní ni ìgbàlà wọ ilé yìí, níwọ̀n bí òun pẹ̀lú ti jẹ́ ọmọ Ábúráhámù.
10. Nítorí Ọmọ Ènìyàn dé láti wá àwọn tí ó nù kiri, àti láti gbà wọ́n là.”
11. Nígbà tí wọ́n sì ń gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó sì tẹ̀ṣíwájú láti pa òwe kan, nítorí tí ó súnmọ Jerúsálémù, àti nítorí tí wọn ń rò pé, ìjọba Ọlọ́run yóò farahàn nísinsin yìí.
12. Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà.
13. Ó sì pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mínà mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ má a ṣòwò títí èmi ó fi dé!’
14. “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jọba lórí wa.’
15. “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́-òwò wọn.
16. “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà mẹ́wá sí i.’
17. “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòótọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’
18. “Èyí èkéjì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mínà rẹ jèrè owó mínà márùnún.’
19. “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ joyè ìlú márùnún!’
20. “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wòó owó mínà rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ-pélébé kan;
21. Nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn: ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’
22. “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn;
23. Èé ha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowó pamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, Èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’