Lúùkù 12:5-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpádì: lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù.

6. Ológoṣẹ́ márùn ún sáà ni a ń tà lówó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run?

7. Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológóṣẹ́ púpọ̀ lọ.

8. “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run:

9. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run.

10. Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ọmọ ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jìn-ín; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jìn-ín.

11. “Nígbà tí wọ́n bá sì mú yín wá sí sínágọ́gù, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn alásẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kínni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kínni ẹ̀yin ó wí:

12. Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”

13. Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”

14. Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, tani ó fi mí jẹ onídájọ́ tàbí olùpí-ogúnn fún yín?”

15. Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì má a sọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”

16. Ó sì pa òwe kan fún wọn, pé, ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso:

17. Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.”

18. Ó sì wí pé, “Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èṣo àti ọrọ̀ mi jọ sí.

19. Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, má a yọ̀.”

20. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, “Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó bèèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti tani nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?”

21. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìsúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

Lúùkù 12