32. Àwọn ará Nínéfè yóò dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, wọn ó sì dá a lẹ́bi: nítorí tí wọn ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jónà; sì kíyèsíi, ẹni tí ó pọ̀jù Jónà lọ ń bẹ níhín-ín yìí.
33. “Kò sí ẹnìkan, nígbà tí ó bá tan fìtílà tan, tí i gbé e sí ìkọ̀kọ̀, tàbí sábẹ́ òṣùwọ̀n, bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọlé baà lè má a rí ìmọ́lẹ̀.
34. Ojú ni ìmọ́lẹ̀ ara: bí ojú rẹ bá mọ́, gbogbo ara rẹ a mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá burú, ara rẹ pẹ̀lú a kún fún òkùnkùn.
35. Nítorí náà kíyèsí i, kí ìmọ́lẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ má ṣe di òkùnkùn.
36. Ǹjẹ́ bí gbogbo ara rẹ bá kún fún ìmọ́lẹ̀, tí kò ní apákan tí ó ṣókùnkùn, gbogbo rẹ̀ ni yóò ní ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí fìtílà bá fi ìtànsán rẹ̀ fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”
37. Bí ó sì ti ń wí, Farisí kan bẹ̀ẹ́ kí ó bá òun jẹun: ó sì wọlé, ó jókòó láti jẹun.
38. Nígbà tí Farisí náà sì rí i, ẹnu yà á nítorí tí kò kọ́kọ́ wẹ ọwọ́ kí ó tó jẹun
39. Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisí a máa fẹ́ fi ara hàn bí ènìyàn mímọ́ ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ.
40. Ẹ̀yin aláìmòye, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú?
41. Kí ẹ̀yin kúkú má a ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsii, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.
42. “Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisí, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá mítì àti rue, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsì fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.