Lúùkù 1:67-72 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

67. Sakaráyà baba rẹ̀ sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì ṣọtẹ́lẹ̀, ó ní:

68. “Olùbùkún ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì;Nítorí tí ó ti bojúwò, tí ó sì ti dá àwọn ènìyàn rẹ̀ nídè,

69. Ó sì ti gbé ìwo ìgbàlà sókè fún waNí ilé Dáfídì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀;

70. (bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ ní ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ típẹ́típẹ́),

71. Pé, a ó gbà wá là lọ́wọ́àwọn ọ̀tá wa àti lọ́wọ́ àwọn tí ó kórira wá;

72. Láti ṣe àánú tí ó ti lérí fún àwọn baba wa,Àti láti rántí májẹ̀mu rẹ̀ mímọ́,

Lúùkù 1