Lúùkù 1:44-63 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Sá wò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀.

45. Alábùkúnfún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́: nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò ṣẹ.”

46. Màríà sì dáhùn, ó ní:“Ọkàn mi yin Olúwa lógo,

47. Ẹ̀mí mi sì yọ̀ sí Ọlọ́run Olùgbàlà mi.

48. Nítorí tí ó ṣíjú wo ìwà ìrẹ̀lẹ̀ọmọbìnrin ọ̀dọ̀ rẹ̀: Sá wò ó,láti ìsinsìn yìí lọ gbogbo ìran ènìyàn ni yóò máa pè mí ní alábùkúnfún.

49. Nítorí ẹni tí ó ní agbára ti ṣe ohun tí ó tóbi fún mi;Mímọ́ sì ni orúkọ rẹ̀.

50. Àánú rẹ̀ sì ń bẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀láti ìrandíran.

51. Ó ti fi agbára hàn ní apá rẹ̀;Ó ti tú àwọn onígberaga ká ní ìrònú ọkàn wọn.

52. Ó ti mú àwọn alágbára kúrò lórí ìtẹ́ wọn,Ó sì gbé àwọn onírẹ̀lè lékè.

53. Ó ti fi ohun tí ó dára kún àwọn tí ebí ń paó sì rán àwọn ọlọ́rọ̀ padà ní òfo.

54. Ó ti ran Ísíráẹ́lì ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́,Ní ìrántí àánú rẹ̀;

55. sí Ábúráhámù àti àwọn ìran rẹ̀ láéláé, baba wa,àti bí ó ti sọ fún àwọn baba wa.”

56. Màríà sì jókòó tì Èlísábétì níwọ̀n oṣù mẹ́ta, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀.

57. Nígbà tí ọjọ́ Èlísabẹ́tì pé wàyí tí yóò bí; ó sì bí ọmọkùnrin kan.

58. Àwọn aládùúgbò, àti àwọn ìbátan rẹ̀ gbọ́ bí Olúwa ti fi àánú ńlá hàn fún un, wọ́n sì bá a yọ̀.

59. Ó sì ṣe, ní ijọ́ kẹjọ wọ́n wá láti kọ ọmọ náà nílà; wọ́n sì fẹ́ sọ orúkọ rẹ̀ ní Sakaráyà, gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba rẹ̀.

60. Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Jòhánù ni a ó pè é.”

61. Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”

62. Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí bàbá rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.

63. Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.

Lúùkù 1