Lúùkù 1:40-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Ó sì wọ ilé Sakaráyà lọ ó sì kí Èlísabẹ́tì.

41. Ó sì ṣe, nígbà tí Èlísábẹ́tì gbọ́ kíkí Màríà, ọlẹ̀ sọ nínú rẹ̀; Èlísábẹ́tì sì kún fún Èmí mímọ́;

42. Ó sì ké ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Alúbùkún fún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkúnfún sì ni ọmọ tí ìwọ yóò bí.

43. Èéṣe tí èmi fi rí irú ojúrere yìí, tí ìyá Olúwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá?

Lúùkù 1