8. Búrẹ́dì yìí ni kí ẹ gbé wá ṣíwájú Olúwa nígbàkugbà, lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé.
9. Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni ín. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.”
10. Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Éjíbítì. Ó jáde lọ láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrin òun àti ọmọ Ísírẹ́lì kan.
11. Ọmọkùnrin arábìnrin Ísírẹ́lì náà sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè: Wọ́n sì mú-un tọ Mósè wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Selomiti, ọmọbìnrin Débírì, ará Dánì).
12. Wọ́n fi í sínú àtìmọ́lé kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.
13. Olúwa sì sọ fún Mósè pé:
14. “Mú asọ̀rọ̀òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fi hàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.
15. Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọbíbí Ísírẹ́lì, bí ó bá ti sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.
17. “ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹmi ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á.
18. Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.