Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátapáta, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú oko àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.