7. Ìgbà méje ni kí o wọ́n omi yìí sí ara ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ kúrò nínú àrùn ara náà kí ó ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ níta gbangba.
8. “Ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, fá gbogbo irun rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, lẹ́yìn èyí ó ti di mímọ́. Lẹ́yìn náà ó le wá sínú ibùdó ṣùgbọ́n kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ méje.
9. Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ kéje: irun orí rẹ̀, irungbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tó kù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.
10. “Ní ọjọ́ kejọ kí ó mú àgbò méjì àti abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n òróró kan.