1. Olúwa sọ fún Mósè pé,
2. “Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú-un tọ àlùfáà wá.
3. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú àrùn ẹ̀tẹ̀ náà.
4. Kí àlùfáà páṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́.
5. Kí àlùfáà pàṣẹ pé kí wọn pa ọ̀kan nínú àwọn ẹyẹ náà sórí omi tí ó mọ́ tó wà nínú ìkòkò amọ̀.
6. Lẹ́yìn náà kí ó ri ààyè ẹyẹ pẹ̀lú igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí a ti pa sínú omi náà.