Léfítíkù 14:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú-un tọ àlùfáà wá.

3. Kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò ní ẹ̀yìn ibùdó bí ara rẹ̀ bá ti yá kúrò nínú àrùn ẹ̀tẹ̀ náà.

4. Kí àlùfáà páṣẹ pé kí a mú ààyè ẹyẹ mímọ́ méjì, igi sídà, òdòdó àti ẹ̀ka hísópù wá fún ẹni tí a fẹ́ wẹ̀ mọ́.

Léfítíkù 14