9. Kí ó fi omi ṣàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
10. “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn agutan tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù,
11. kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká
12. Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì tò ègé ẹran náà, orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ.
13. Kí ó fi omi san nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa