Léfítíkù 1:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn agutan tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù,

11. kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Árónì tí í se àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká

12. Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì tò ègé ẹran náà, orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ.

13. Kí ó fi omi san nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun tí a fi iná se, àní òórùn dídùn sí Olúwa

14. “ ‘Bí ọrẹ tí a fẹ́ fi fún Olúwa bá jẹ́ ti àwọn ẹyẹ, kí ó mú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé

15. Kí àlùfáà mu wá sí ibi pẹpẹ, kí ó yín in lọ́rùn, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, kí ó sì ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.

Léfítíkù 1