13. Ẹ máa fara dàá fún ara yín, ẹ sì máa dáríji ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn sí ẹnìkan: bí Kírísítì ti dáríjì yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó máa ṣe pẹ̀lú.
14. Àti borí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tí í ṣe àmùrè ìwà pípé.
15. Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́.
16. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kírísítì máa gbé inú yín lí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ sì máa gba ara yín, níyànjú nínú Sáàmù, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa fi oore ọ̀fẹ́ kọrin ní ọkàn yín sí Olúwa
17. Ohunkóhun tí ẹ̀yín bá sì ń ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn ní orúkọ Jésù Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run baba nípasẹ̀ rẹ̀.
18. Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ nínú Olúwa.
19. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn.
20. Ẹ̀yin ọmọ ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín ní ohun gbogbo: nítorí èyí dára gidigi nínú Olúwa.
21. Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, kí wọn má bà á rẹ̀wẹ̀sì.
22. Ẹ̀yin ẹrú, ẹ gbọ́ ti àwọn olówó yín nípa ti ara ní ohun gbogbo; kì í ṣe ní àrojú ṣe, bí àwọn aláṣehàn ènìyàn; ṣugbọ́n ní òtítọ́ inú, ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run: