Kólósè 1:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ sọ̀kan.

18. Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí Òun lè ní ipo tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun.

19. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun lè máa gbé nínú rẹ̀.

Kólósè 1