Júdà 1:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Bákan náà ni àwọn wọ̀nyí ń sọ ara wọn di èérí nínú àlá wọn, wọ́n ń gan ìjoye, wọn sì ń sọ̀rọ̀ búbúrú sí àwọn ọlọ́lá.

9. Ṣùgbọ́n Mákẹ́lì, olórí awọn ańgẹ́lì, nígbà tí ó ń bá Èṣù jiyàn nítórí òkú Mósè, kò sọ ọ̀rọ̀ òdì sí i; Ṣùgbọ́n ó wí pé, “Olúwa bá ọ wí.”

10. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí n sọ̀rọ̀ òdì sí ohun gbogbo ti kò yé wọn: ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí wọn mọ̀ nípa ìròfún-ara, bí ẹranko tí kò ní ìyè, nípaṣẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n di ẹni ìparun.

Júdà 1