Jóṣúà 5:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà náà ní Olúwa wí fún Jóṣúà pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Éjíbítì kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gílígálì títí ó fi di òní yìí.

10. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹ́rìnlá (14) oṣù náà (oṣù kẹ́rin) (4) nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gílígálì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ọdún Àjọ-ìrékọjá.

11. Ní ọjọ́ kéjì Àjọ-ìrékọjá, ní ọjọ́ náà gan-an ni, wọ́n jẹ nínú; àwọn irè oko ilẹ̀ náà: àkàrà aláìwú, àti ọkà yíyan.

12. Mánà náà sì tan ní ọjọ́ kéjì tí wọ́n jẹ oúnjẹ tí ilẹ̀ náà mú jáde; kò sì sí mánà kankan mọ́ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n ní ọdún náà wọ́n jẹ irè oko ilẹ̀ Kénánì.

13. Nígbà tí Jóṣúà sún mọ́ Jẹ́ríkò, ó wo òkè ó sì rí ọkùnrin kan tí ó dúró ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú idà ní ọwọ́ rẹ̀. Jóṣúà sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Ǹjẹ́ ìwọ wà fún wa tàbí fún ọ̀ta a wa?”

14. “Kì í ṣe fún èyíkéyìí ó fèsì, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí olórí ogun Olúwa ni mo wá nísinsin yìí.” Nígbà náà ni Jóṣúà sì wólẹ̀ ní iwájú u rẹ̀ ní ìbẹ̀rù, ó sì bi í léèrè, “Kí ni Olúwa ní í sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?”

15. Olórí ogun Olúwa sì dá a lóhùn pé, “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹṣẹ̀ rẹ, nítorí pé ibi tí ìwọ dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀.

Jóṣúà 5