7. Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárin yín àti àwọn ará Éjíbítì, ó sì mú òkun wá sí orí i wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Éjíbítì. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní ihà fún ọjọ́ pípẹ́.
8. “ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Ámórì tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jọ́dánì. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò ní wájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn.
9. Nígbà tí Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù, múra láti bá Ísírẹ́lì jà, ó ránṣẹ́ sí Bálámù ọmọ Béóríù láti fi yín bú.
10. Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Bálámù, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín ṣíwájú àti ṣíwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
11. “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ ré kọjá Jọ́dánì, tí ẹ sì wá sí Jẹ́ríkò. Àwọn ará ìlú Jẹ́ríkò sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Ámórì, Pérísì, Kénánì, Hítì, Gígásì, Hífì àti Jébúsì. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.
12. Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọbá Ámórì méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín.
13. Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà ólífì tí ẹ kò gbìn.’