13. Ní àfikún wọ́n sì fún àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ní Hébúrónì (ọ̀kannínú ìlú ààbò fún àwọn apàníyàn) pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù rẹ̀, Líbínà,
14. Játírì, Ésítẹ́móà,
15. Hólónì àti Débírì,
16. Háínì, Jútà àti Bẹti-Sẹ́mẹ́sì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn. Ìlú mẹ́sàn án láti ara ẹ̀yà méjì wọ̀nyí.
17. Láti ara ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni wọ́n ti fún wọn ní Gíbíónì, Gẹ́bà,
18. Ánatótì àti Álímónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.”
19. Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Árónì, jẹ́ mẹ́talá, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn.
20. Ìyòókù ìdílé Kóhátì tí ó jẹ́ ọmọ Léfì ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù.
21. “Ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù wọ́n fún wọn ní Ṣẹ́kẹ́mù (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) ati Gésérì,
22. Kíbásáímù àti Bẹti-Hórónì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.
23. Láti ara ẹ̀yà Dánì ní wọ́n ti fún wọn ní Élítékè Gíbátónì,