Jóṣúà 21:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báyìí ni olórí ìdílé àwọn ọmọ Léfì lọ bá Élíásárì àlùfáà, Jóṣúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn ìdílé ẹ̀yà Ísírẹ́lì

2. Ní Sílò, ní Kénánì, wọn sọ fún wọn pé, “Olúwa pàṣẹ nípasẹ̀ Mósè pé kí wọn fún wa ní ìlú láti máa gbé àti ilẹ̀ pápá oko tútù fún ẹran ọ̀sìn wa.”

3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì fún àwọn ọmọ Léfì ní àwọn ìlú wọ̀nyí, àti ilẹ̀ pápá oko tútù lára ilẹ̀ ìní ti wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

4. Ìpín kìn-ín-ni wà fún àwọn ọmọ Kóhátì, ní agbo ilé, agbo ilé. Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Árónì àlùfáà ni a pín ìlú mẹ́talá fún láti ara Símónì àti Bẹ́ńjámínì.

5. Ìyòókù àwọn ọmọ Kóhátì ni a pín ìlú mẹ́wàá fún láti ara ẹ̀yà Éfúráímù, Dánì àti ìdajì Mánásè.

Jóṣúà 21