Jóòbù 9:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Kíyèsí i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi,èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwáju,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.

12. Kiyèsí i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà?Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?

13. Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn,àwọn oní rànlọ́wọ́ ti Ráhábù a sì tẹriba lábẹ́ rẹ̀.

14. “Kí ní ṣe tí èmi ò fi dá a lóhùn?Tí èmi kò fi máa fi ọ̀rọ̀ àwàwí mi ṣe àwsíyé fún-un?

15. Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi,èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn,ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.

Jóòbù 9