Jóòbù 5:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye,ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.

3. Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lulẹ̀,ṣùgbọ́n lójú kan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.

4. Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu,a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè,bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.

5. Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa jẹẹran, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀kún lọ kó,àwọn ìgárá sì gbé ohun ìní wọn mì.

6. Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni,tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.

7. Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà,gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.

8. “Sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní èmi lè máa ṣe àwárí,ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi lè máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.

9. Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí,ohun ìyanu láìní iye.

10. Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayétí ó sì ń rán omi sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

11. Láti gbé àwọn orilẹ̀ èdè lékèkí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.

12. Ó yí ìmọ̀ àwọn alárèékérekè po,bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdàwọ́lé wọn sẹ.

Jóòbù 5