Jóòbù 34:33-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Íṣe bí ti inú rẹ̀ pe òun ó san ẹ̀ṣẹ̀ padà?Ǹjẹ́ òun yóò san án padà bíìwọ bá kọ̀ ọ́ láti jẹ́wọ́ tàbíìwọ ìbá fẹ́ kì í ṣe èmi; Pẹ̀lúpẹ̀lú ohun tí ìwọ mọ̀, sọ ọ!

34. “Àwọn ènìyàn amòye yóò wí fúnmi, àti pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí í ṣe ọlọ́gbọ́n tí ó sì gbọ́ mi pé,

35. ‘Jóòbù ti fi àìmọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ṣealáìgbọ́n.’

36. Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jóòbù wò déòpin, nítorí ìdahùn rẹ̀ dà bí i ti ènìyàn búburú:

37. Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ópàtẹ́wọ́ ní àárin wa, ó sì sọọ̀rọ̀ di púpọ̀ sí Ọlọ́run.”

Jóòbù 34