Jóòbù 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yìn èyí ní Jóòbù yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré

2. Jóòbù sọ, ó sì wí pé:

3. “Kí ọjọ́ tí a bi mi kí ó di ìgbàgbé,àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A loyún ọmọkùnrin kan!’

4. Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn,kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá;bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.

5. Kí òkùnkùn àti òjìjì ikú fi ṣe ti ara wọn;kí àwọ-sánmọ̀ kí ó bà lé e;kí ìṣúdúdú ọjọ́ kí ó pa láyà.

Jóòbù 3