25. O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idàdídán ní ń jáde láti inú òróòrowá: Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀.
26. Òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́fún ìṣúra rẹ̀; iná ti a kò fẹ́ níyóò jó o run: yóò sì jẹ èyí tí ókù nínú àgọ́ rẹ̀ run.
27. Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóòsì dìde dúró sí i.
28. Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohunìní rẹ̀ yóò ṣàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.
29. Èyi ni ìpín ènìyàn buburú látiọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí ayàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”