14. Àwọn alájọbí mi fà sẹ́yìn, àwọnafaramọ́ ọ̀rẹ́ mi sì di onígbàgbé mi.
15. Àwọn ará inú ilé mi àti àwọnìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
16. Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá milóhùn; mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
17. Ẹ̀mí mi sú àyà mi, àti òòrun misú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
18. Àní àwọn ọmọdé kùnrin fi míṣẹ̀sín: Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
19. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mikórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
20. Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ẹran ara mi, mo sì bọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
21. “Ẹ ṣáànú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.