Jóòbù 18:6-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́rẹ̀, fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.

7. Ìrìn ẹṣẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọn;ìmọ́lẹ̀ òun tìkárarẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.

8. Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkararẹ̀ ó ti bọ́ sínúàwọ̀n, ó sì rìn lóri okùn dídẹ.

9. Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.

10. A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sìwà ọ̀fìn fún un lojú ọ̀nà.

11. Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo,yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.

12. Àìlera rẹ̀ yóò di pipa fún ebi,ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.

13. Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; àkọ́bí ikú niyóò jẹ agbára rẹ̀ run.

14. A ó fà á tu kurò nínú àgọ́ tí ógbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.

15. Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀èyí tí í ṣe tirẹ̀; ìmí ọjọ́ ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.

16. Gbòngbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀, a ósì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.

17. Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé,kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.

18. A ó sì lée láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inúòkùnkùn, a ó sì lé e kúrò ní ayé.

19. Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọnínu àwọn ènìyàn rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni kòsí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.

Jóòbù 18