Jóòbù 13:21-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kurò lára mi,má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.

22. Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn;Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

23. Mélòó ní àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi?Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.

24. Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́,tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?

25. Ìwọ ó fa ewé ya ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún?Ìwọ a sì máa lépa àkémọ́lẹ̀ pòròpórò gbígbẹ?

26. Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi,o sì mú mi ní àìṣedéédéé èwe mi.

Jóòbù 13