13. “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi,kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ohun tí ńbọ̀ wá íbá mi, kí ó máa bọ̀.
14. Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi èyín mibu ẹran ara mi jẹ, Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?
15. Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e;Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.
16. Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi,Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.