Jòhánù 6:47-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, ó ní ìyè àìnípẹ̀kun.

48. Èmi ni oúnjẹ ìyè.

49. Àwọn baba yín jẹ mánà ní ihà, wọ́n sì kú.

50. Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, kí ènìyàn lè máa jẹ nínú rẹ̀ kí ó má sì kú.

Jòhánù 6