1. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò; Jésù sì gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù.
2. Adágún omi kan sì wà ní Jérúsálẹ́mù, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Bẹtiṣáídà ní èdè Hébérù, tí ó ní ìloro márùn-ún.
3. Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dúbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti alárùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi.
4. Nítorí angẹ́lì a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú àrùnkárùn tí ó ní.
5. Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjìdínlógójì.
6. Bí Jésù ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”
7. Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ ṣíwájú mi.”
8. Jésù wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.”
9. Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn.Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi.
10. Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”
11. Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”
12. Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”
13. Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jésù ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.
14. Lẹ́yìn náà, Jésù rí i ní tẹ́ḿpìlì ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má se dẹ́sẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!”
15. Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jésù ni ẹni tí ó mú òun láradá.
16. Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jésù, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí Ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi.