Jòhánù 19:39-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Níkodémù pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru lákọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjíá àti álóè wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́rún lítà.

40. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn.

41. Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì titun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tíì tẹ́ ẹnìkan sí rí.

42. Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jésù sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; nítorí ibojì náà wà nítòòsí.

Jòhánù 19