24. Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé-mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,“Wọ́n pín aṣọ mi láàárin ara wọn,wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ogun ṣe.
25. Ìyá Jésù àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Màríà aya Kílópà, àti Màríà Magidalénì sì dúró níbi àgbélébùú,
26. Nígbà tí Jésù rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!”
27. Lẹ́yìn náà ni ó sì wí fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ!” Láti wákàtí náà lọ ni ọmọ-ẹ̀yìn náà sì ti mú un lọ sí ilé ara rẹ̀.
28. Lẹ́yìn èyí, bí Jésù ti mọ̀ pé, a ti parí ohun gbogbo tán, kí ìwé mímọ́ bà á lè ṣẹ, ó wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ mí.”
29. Ohun èlò kan tí ó kún fún ọtí kíkan wà níbẹ̀, wọ́n tẹ kànrìnkàn bọ inú rẹ̀, wọ́n sì fi lé ori igi híssópù, wọ́n sì nà án sí i lẹ́nu.
30. Nígbà tí Jésù sì ti gba ọtí kíkan náà, ó wí pé, “Ó parí!” Ó sì tẹ orí rẹ̀ ba, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.
31. Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má baà wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi, (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà) nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pílátù pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò.
32. Nítorí náà, àwọn ọmọ ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ egungun itan ti èkínní, àti ti èkejì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀.
33. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀:
34. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójú kan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.