Jòhánù 18:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jésù léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

20. Jésù dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù, àti ní Tẹ́ḿpìlì níbi tí gbogbo àwọn Júù ń pé jọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀.

21. Èé ṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”

Jòhánù 18