17. Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Lásárù jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rí sí i.
18. Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí.
19. Nítorí náà àwọn Farisí wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”
20. Àwọn Gíríkì kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ:
21. Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Fílípì wá, ẹni tí í ṣe ará Bẹtisáídà tí Gálílì, wọ́n sì ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jésù!”
22. Fílípì wá, ó sì sọ fún Ańdérù; Ańdérù àti Fílípì wá, wọ́n sì sọ fún Jésù.
23. Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo.
24. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé àlìkámà bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, a sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso.
25. Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun.
26. Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.