Jòhánù 11:46-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

46. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisí lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jésù ṣe.

47. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí pe ìgbìmọ̀ jọ, wọ́n sì wí pé,“Kínni àwa ń ṣe? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì.

48. Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́: àwọn ará Rómù yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.”

49. Ṣùgbọ́n Káyáfà, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá!

Jòhánù 11