Jòhánù 11:31-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Màríà tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣebí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀.

32. Nígbà tí Màríà sì dé ibi tí Jésù wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbáṣe pé ìwọ ti wà níhín-ín, arákùnrin mi kì bá kú.”

33. Nígbà tí Jésù rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́.

34. Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.”

35. Jésù sọkún.

36. Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!”

37. Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣeé kí ọkùnrin yìí má kú bí?”

38. Nígbà náà ni Jésù tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀.

39. Jésù wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!”Màtá, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí: nítorí pé ó di ijọ́ kẹrin tí ó tí kú.”

40. Jésù wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ ó rí ògo Ọlọ́run?”

41. Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jésù sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi.

42. Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo: ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn baà lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.”

Jòhánù 11