Jòhánù 10:17-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á.

18. Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

19. Nítorí náà ìyapa tún wà láàrin àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.

20. Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”

21. Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mi èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”

22. Ó sì jẹ́ àjọ̀dún ìyàsímímọ́ ní Jérúsálẹ́mù, ìgbà òtútù ni.

23. Jésù sì ń rìn ní tẹ́mpílì, ní ìloro Sólómónì,

24. Nítorí náà àwọn Júù wá dúró yí i ká, wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ó ti mú wa ṣe iyèméjì pẹ́ tó? Bí ìwọ bá ni Kírísítì náà, wí fún wa gbangba.”

25. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Èmi ti wí fún yín, ẹ̀yin kò sì gbàgbọ́; iṣẹ́ tí èmi ń ṣe lórúkọ Baba mi, àwọn ni ó ń jẹ́rìí mi.

26. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbàgbọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí nínú àwọn àgùntàn mi, gẹ́gẹ́ bí mo tí wí fún yín.

27. Àwọn àgùntàn mi ń gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn:

28. Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọn kì yóò sì ṣègbé láéláé, kò sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.

29. Baba mi, ẹni tí ó fi wọ́n fún mi pọ̀ ju gbogbo wọn lọ; kò sì sí ẹni tí ó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba mi.

Jòhánù 10