Jeremáyà 9:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóróó ń sọ ẹ̀tàn; oníkálukú sì ńfi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà síaládúgbò rẹ̀; ní inúọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.

9. Èmi kì yóò háa fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?”ni Olúwa wí.“Èmi kì yóò ha gbẹ̀san arami lórí irú orílẹ̀ èdè yìí bí?”

10. Èmi yóò sì sunkún, pohùnréréẹkún fún àwọn òkè; àti ẹkúnìrora lórí pápá oko ihà wọ̀n-ọn-nì.Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sìkọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbeẹran ọ̀sìn, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀runsì ti sá lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.

11. “Èmi yóò sì sọ Jérúsálẹ́mù di òkìtìàlàpà àti ìhò àwọn ìkokò.Èmi ó sì sọ ìlú Júdà di ahorotí ẹníkẹ́ní kò sì ní le è gbé.”

12. Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? È é ṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí ihà, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?

Jeremáyà 9