Jeremáyà 7:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jérémáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.

2. “Dúró ní ẹnu ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí:“ ‘Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Júdà tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa.

3. Èyi ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí.

4. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa, ilé Tẹ́ḿpìlì Olúwa!”

Jeremáyà 7