9. Èyí ni ohun tí Olúwa Àwọn ọmọ ogun wí:“Jẹ́ kí wọn pesẹ́ ìyókù Ísírẹ́lìní tónítóní bí àjàrà;na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí igẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èṣo àjàrà jọ.”
10. Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àtití mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta niyóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọnti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
11. Èmi kún fún ìbínú Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra.“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àtisórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kórawọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a òmú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbótí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12. Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,oko wọn àti àwọn aya wọn,nígbà tí èmi bá na ọwọ́ misí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”ni Olúwa wí.