3. Olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbógun tì wọ́n.Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”
4. “Múra sílẹ̀ láti bá a jagun!Dìde, kí a kọ lù ú ní ìgbà ọ̀sán!Àmọ́ ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.
5. Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọ lù ú ní àṣálẹ́kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”
6. Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí:“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jérúsálẹ́mù ká.A gbọdọ̀ fi ìyà jẹ orílẹ̀ èdè yìínítorí pé ó kún fún ìrẹ́nijẹ.
7. Gẹ́gẹ́ bí kàǹga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.Ìwà ipá àti ìparun ń tún dún padà nínú rẹ̀;nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.
8. Ìwọ Jérúsálẹ́mù, gba ìkìlọ̀kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,tí kò ní ní olùgbé.”