Jeremáyà 51:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ifẹ́ wúrà ni Bábílónì ní ọwọ́ Olúwa;ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí.Gbogbo orílẹ̀ èdè mu ọtí rẹ̀,wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀.

8. Bábílónì yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́;sunkún fún un! Wá báàmù fún ìrora rẹ,bóyá yóò le wo ọ́ sàn.

9. “ ‘À bá ti wo Bábílónì sàn,ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀,kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè,ó ga àní títí dé òfurufù.’

10. “ ‘Olúwa ti dá wa láre,wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Síónì ohun tí OlúwaỌlọ́run wa ti ṣe.’

Jeremáyà 51