Jeremáyà 51:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀jáde tàbí kí o di ìhámọ́ra rẹ̀;má ṣe dá àwọn ọdọ́mọkùnrinsí, pátapáta ni kí o pa àwọn ọmọ ogun rẹ̀.

4. Gbogbo wọn ni yóò ṣubúní Bábílónì tí wọn yóò sìfarapa yánna yànna ní òpópónà.

5. Nítorí pé Júdà àti Ísírẹ́lì niỌlọ́run wọn tí í se Olúwa alágbárakò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọnkún fún kìki ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.

Jeremáyà 51