Jeremáyà 50:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi sẹ́nu Jeremáyà láti sọ fún ará ilẹ̀ Bábílónì:

2. “Ẹ sọ ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde,kí ẹ sì gbé àṣíà sókè.Ẹ kede, ẹ má sì ṣe bòó wí pé,‘a kó Bábílónì,ojú tí Bélì,a fọ́ Merodákì túútúú,ojú ti àwọn ère rẹ̀,a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’

3. Àwọn ìlú ní apá àríwá yóòsì máa gbógun tì wọ́n.Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóòsá kúrò ní ìlú yìí.

4. “Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”ni Olúwa wí,“Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jùmọ̀ wá,àwọn, àti àwọn ọmọ Júdà,wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́ri Olúwa Ọlọ́run wọn

Jeremáyà 50