12. Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ife náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mu un.
13. Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bósírà yóò bayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ẹgún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”
14. Èmi ti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa:A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀ èdè láti sọ.Ẹ kó ara yín jọ láti dojúkọ ọ́, ẹ dìde fún ogun.
15. “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ dikékeré láàrin orílẹ̀ èdè gbogbo;ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn ènìyàn.
16. Ìpayà tí ìwọ ti fà sínúìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ;ìwọ tí ń gbé ní pàlàpáláàpáta tí o jòkó lórí ìtẹ́ gígasíbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì;láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,”ni Olúwa wí.
17. “Édómù yóò di ahorogbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sìfi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ