Jeremáyà 48:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran,ìwọ tí ń gbé ní Áróà.Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà‘kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’

20. Ojú ti Móábù nítorí tí a wó o lulẹ̀,ẹ hu, sì kígbe síta!Ámónì kéde péa pa Móábù run.

21. Ìdájọ́ ti dé sí Pílátéùsórí Hólónì, Jáhásà àti Mẹ́fátì,

22. sórí Díbónì, Nébò àti Bẹti Díbílátaímù

23. sórí Kíríátaímù, Bẹti Gámù àti Bẹti Méónì,

24. sórí Kéríótì àti Bóásì,sórí gbogbo ìlú Móábù, nítòsí àti ní ọ̀nà jínjìn.

25. A gé ìwo Móábù kúrò,apá rẹ̀ dá,”ni Olúwa wí.

26. “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutínítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa,jẹ́ kí Móábù pàfọ̀ nínú èébì rẹ̀,kí ó di ẹni ẹ̀gàn.

27. Ǹjẹ́ Ísírẹ́lì kò di ẹni ẹ̀gan rẹ?Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olètó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́nígbákùúgbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

28. Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrin àwọn òkúta,ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Móábù.Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀sí ẹnu ihò.

29. “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Móábù:àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.

Jeremáyà 48